Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 10:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Báálì àti Áṣítórétù àti àwọn òrìṣà Árámù, òrìṣà Ṣídónì, òrìṣà Móábù, òrìṣà àwọn ará Ámónì àti òrìṣà àwọn ará Fílístínì. Nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn-ín mọ́,

7. ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Fílístínì àti Ámónì láti jẹ ẹ́ ní ìyà.

8. Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́li tí ó wà ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì ní ilẹ̀ àwọn ará Ámórì lára (èyí nì ní Gílíádì).

9. Àwọn ará Ámónì sì la odò Jọ́dánì kọjá láti bá Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn ará ilé Éfúráímù jagun: Ísírẹ́lì sì dojú kọ ìpọ́njú tó lágbára.

10. Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Báálì.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 10