Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 10:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Éjíbítì, Ámórì, Ámónì, Fílístínì,

12. àwọn ará Sídónì, Ámélékì pẹ̀lú Móánì ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn?

13. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́.

14. Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!”

15. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dá Olúwa lóhùn pé, “Àwá ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ ná ní àsìkò yìí.”

16. Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàárin wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Ísírẹ́lì mọ́.

17. Nígbà tí àwọn ará Ámónì kógun jọ ní Gílíádì láti bá Ísírẹ́lì jà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbárajọpọ̀ wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mísípà.

18. Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gílíádì wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ sígun si àwọn ará Ámónì ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gílíádì.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 10