Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 10:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ikú Ábímélékì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Ísákárì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ní Sámírì tí ó wà ní òkè Éfúráímù ni ó gbé.

2. Ó ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́talélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Sámírì.

3. Jáírì ti ẹ̀yà Gílíádì ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Ísirẹ́lì ní ọdún méjìlélógún.

4. Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó ní gún ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gílíádì, tí a pe orúkọ wọn ní Háfótì Jáírì títí di òní.

5. Nígbà tí Jáírì kú wọ́n sin ín sí Kámónì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 10