Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:19-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọrẹ tí ó kó wá ní àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) sékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

20. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ sékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

21. Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

22. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

23. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-un àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-un tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Nètaníẹ́lì ọmọ Súárì.

24. Élíábù ọmọ Hélónì, olórí àwọn ọmọ Sébúlónì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹ́ta.

25. Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọn rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì,

26. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

27. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

28. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

29. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn ún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élíábù ọmọ Hélónì.

30. Élíṣúrì ọmọ Ṣédéúrì olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.

31. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

32. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

33. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7