Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Wọ́n kúrò ní Márà wọ́n sì lọ sí Élímù, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.

10. Wọ́n kúrò ní Élímù wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.

11. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú ihà Ṣínì.

12. Wọ́n kúrò nínú ihà Ṣínì wọ́n sì pàgọ́ sí ihà Dófákà.

13. Wọ́n kúrò ní Dófákà wọ́n sì pàgọ́ ní Álúṣì.

14. Wọ́n kúrò ní Álúṣì wọ́n sì pàgọ́ ní Réfídímù níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33