Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní ìwájú Háhírótù, wọ́n sì la àárin òkun kọjá lọ sí ihà: Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní ihà Étamù, wọ́n sì pàgọ́ sí Márà.

9. Wọ́n kúrò ní Márà wọ́n sì lọ sí Élímù, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.

10. Wọ́n kúrò ní Élímù wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.

11. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú ihà Ṣínì.

12. Wọ́n kúrò nínú ihà Ṣínì wọ́n sì pàgọ́ sí ihà Dófákà.

13. Wọ́n kúrò ní Dófákà wọ́n sì pàgọ́ ní Álúṣì.

14. Wọ́n kúrò ní Álúṣì wọ́n sì pàgọ́ ní Réfídímù níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.

15. Wọ́n kúrò ní Refídímù wọ́n sì pàgọ́ ní ihà Ṣínáì.

16. Wọ́n kúrò ní ihà Ṣínáì wọ́n sì pàgọ́ ní Kabirotu-Hátafà.

17. Wọ́n kúrò ní Kabirotu-Hátafà wọ́n sì pàgọ́ ní Hásérótì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33