Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:44-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Wọ́n kúrò ní Óbótù wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Ábárímù, ní agbégbé Móábù.

45. Wọ́n kúrò ní Íyímù wọ́n sì pàgọ́ ní Díbónì-Gádì.

46. Wọ́n kúrò ní Dibónì-Gádì wọ́n sì pàgọ́ ní Alimoni-Díbílátamù.

47. Wọ́n kúrò ní Alimoni-Díbílátaímù wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Ábárímù lẹ́bá Nébò.

48. Wọ́n kúrò ní orí òkè Ábárímù wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì ní ìkọjá Jẹ́ríkò.

49. Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jọ́dánì láti Bẹti-Jéíóù títí dé Abeli-Sítímù

50. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, lẹ́bá Jọ́dánì, létí Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé,

51. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jọ́dánì lọ sí Kénánì,

52. Lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀.

53. Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú ún rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín.

54. Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ ti wọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33