Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrin wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Rámésesì wọ́n sì pàgọ́ sí Ṣúkótù.

6. Wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étamù, ní ẹ̀bá ihà.

7. Wọ́n kúrò ní Étamù, wọ́n padà sí Háhírótù sí ìlà oòrùn Báálì ti Ṣéfónì, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Mégídólù.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33