Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Íjibítì jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.

2. Mósè sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa; Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò láti Rámésesì ní ọjọ́ kẹ́ẹdógún osù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọja. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Éjíbítì.

4. Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrin wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Rámésesì wọ́n sì pàgọ́ sí Ṣúkótù.

6. Wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étamù, ní ẹ̀bá ihà.

7. Wọ́n kúrò ní Étamù, wọ́n padà sí Háhírótù sí ìlà oòrùn Báálì ti Ṣéfónì, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Mégídólù.

8. Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní ìwájú Háhírótù, wọ́n sì la àárin òkun kọjá lọ sí ihà: Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní ihà Étamù, wọ́n sì pàgọ́ sí Márà.

9. Wọ́n kúrò ní Márà wọ́n sì lọ sí Élímù, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.

10. Wọ́n kúrò ní Élímù wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.

11. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú ihà Ṣínì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33