Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 32:31-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì dáhùn pé, “Iránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ.

32. A máa rékọjá níwájú Olúwa lọ sí Kénánì pẹ̀lú ìhámọ́ra, ṣùgbọ́n ẹrù tí a jogún yóò wà ní ẹ̀bá Jọ́dánì.”

33. Nígbà náà Mósè fún àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ọmọ Jóṣẹ́fù ìjọba Ṣíhónì ọba àwọn ọmọ Ámórì àti ìjọba Ógù ọba Básánì ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbégbé tí ó yí i ka.

34. Àwọn ará Gádì wọ́n kọ́ Dídónì, Átarótù, Áróérì;

35. Pẹ̀lú Átírótù Ṣófánì, Jásérì, àti Jógbénà:

36. Pẹ̀lú Bétínímírà, àti Bétí-Áránì ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn.

37. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì kọ́ Hésíbónì, Élíálì, Kíríátaímù,

38. pẹ̀lú Nébò pẹ̀lú Báálì-Méónì, (“Wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn”) àti Síbímà. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.

39. Àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè lọ sí Gílíádì, wọ́n sì lé àwọn ọmọ Ámórì tí ó wà níbẹ̀.

40. Mósè sì fi àwọn ọmọ Gílíádì fún àwọn ọmọ Mákírì àwọn ìrán Mánásè, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀.

41. Jáírì, ọmọ Mánásè gba ibùjókòó wọn, ó sì pè wọ́n ní Háfótù Jáírì.

42. Nébà gbà Kénátì àti àwọn ìtẹ̀dó rẹ̀, ó sì pè é ní Nóbà lẹ́yìn orúkọ ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 32