Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 31:47-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

48. Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọrọọrún wá sọ́dọ̀ Mósè.

49. Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ìkọkan tó dín.

50. Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka: àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”

51. Mósè àti Élíásárì àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ ọ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.

52. Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mósè àti Élíásárì, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì.

53. Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀.

54. Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú Àgọ́ Ìpàdé fún ìrántí àwọn Ísírẹ́lì níwájú Olúwa.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 31