Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 31:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Inú bí Mósè sí àwọn olórí ọmọ ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1000) àti olórí ọrọrún (1000) tí wọ́n ti ogun dé.

15. Mósè sì bèèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?

16. Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bálámù, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Ísírẹ́lì padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Péórì, nibi tí àjàkálẹ̀-àrùn ti kọlu àwọn ènìyàn Olúwa.

17. Nísinsìnyìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,

18. Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì sún mọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.

19. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.

20. Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”

21. Élíásárì àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mósè.

22. Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé.

23. Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

24. Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 31