Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 3:45-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Tèmi ni àwọn ọmọ Léfì. Èmi ni Olúwa.

46. Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Ísírẹ́lì tó ju iye àwọn ọmọ Léfì lọ,

47. ìwọ yóò gba sẹ́kẹ́lì márùn ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gérà.

48. Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Ísírẹ́lì tó lé yìí, ni kí o kó fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.

49. Nígbà náà ni Mósè gba owó ìràpádà àwọn ènìyàn tó sẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì ti ra àwọn yóòkù padà.

50. Mósè sì gba egbéje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

51. Mósè sì kó owó ìràpadà yìí fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti paá láṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 3