Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 3:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀n yìí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

4. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sínáì, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Élíásárì àti Ítamárì ló sisẹ́ àlùfáà nígbà ayé Árónì baba wọn.

5. Olúwa sọ fún Mósè pé,

6. “Kó ẹ̀yà Léfì wá, kí o sì fà wọ́n fún Árónì àlùfáà láti máa ràn-án lọ́wọ́.

7. Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní Àgọ́ Ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́.

8. Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú Àgọ́ Ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.

9. Fi ẹ̀yà Léfì jìn Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Árónì nínú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10. Kí o sì yan Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”

11. Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

12. “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Léfì láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì. Ti èmi ni àwọn ọmọ Léfì,

13. nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 3