Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 3:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gásónì nínú Àgọ́ Ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

26. aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

27. Ti Kóhátì ní ìdílé Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì, wọ̀nyí ni ìran Kóhátì

28. Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ta, (8,600) tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.

29. Àwọn ìdílé Kóhátì yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúṣù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.

30. Olórí àwọn ìdílé Kóhátì ni Élísáfì ọmọ Yúsíélì.

31. Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tabílì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

32. Élíásárì ọmọ Árónì àlùfáà ni alákóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Léfì. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

33. Ti Mérárì ni ìran Málì àti Múṣì, àwọn ni ìran Mérárì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 3