Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 3:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

14. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè ní ihà Ṣínáì pé,

15. “Ka àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè”

16. Mósè sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

17. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

18. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gáṣónì:Líbínì àti Ṣíméhì.

19. Àwọn ìdílé Kóhátì ni:Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì.

20. Àwọn ìdílé Mérárì ni:Málì àti Músì.Wọ̀nyí ni ìdílé Léfì gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn:

21. Ti Gáṣónì ni ìdílé Líbínì àti Ṣíméhì; àwọn ni ìdílé Gásónì.

22. Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).

23. Àwọn ìdílé Gáṣónì yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀ oòrùn lẹ́yìn àgọ́.

24. Olórí àwọn ìdílé Gáṣónì ni Eliásáfì ọmọ Láélì.

25. Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gásónì nínú Àgọ́ Ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

26. aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 3