Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 29:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

38. Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

39. “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”

40. Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbogbo ohun tí Olúwa ti paláṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 29