Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 29:26-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. “ ‘Àti ní ọjọ́ kárùn un, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

27. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà.

28. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

29. “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

30. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

31. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

32. “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù.

33. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèṣè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

34. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

35. “ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpèjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

36. Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù.

37. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

38. Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

39. “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”

40. Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbogbo ohun tí Olúwa ti paláṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 29