Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 29:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu

23. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù.

24. Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

25. Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

26. “ ‘Àti ní ọjọ́ kárùn un, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

27. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà.

28. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

29. “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

30. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

31. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 29