Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 25:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà, ti yí ìbinú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrin wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.

12. Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.

13. Òun àti irú ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

14. Orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí a pa pẹ̀lú obìnrin Mídíánì náà ni Símírì, ọmọ Ṣálù, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Símónì.

15. Orúkọ ọmọbìnrin Mídíánì náà tí a pa ni Kósíbì ọmọbìnrin Súrù, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Mídíanì.

16. Olúwa sì tún sọ fún Mósè pé,

17. “Ka àwọn ará Mídíánì sí ọ̀ta, kí o sì pa wọ́n,

18. nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Péórì, àti arábìnrin wọn Kósíbì ọmọbìnrin ìjòyè Mídíánì kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-àrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Péórì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 25