Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 24:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. ‘Kó dà bí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?

14. Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

15. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe:“Òwe Bálámù ọmọ Béórì,òwe ẹnì tí ojú rẹ̀ ríran kedere,

16. òwe ẹni kan tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,tí ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ẹni gíga jùlọ,tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì sí:

17. “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí,Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù;yóò yọ jáde láti Ísírẹ́lì.Yóò tẹ̀ fọ́ orí Móábù,yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Ṣéétì.

18. Wọn yóò borí Édómù;yóò ṣẹ́gun Ṣéérì ọ̀ta rẹ̀,ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì yóò dàgbà nínú agbára.

19. Olórí yóò jáde láti Jákọ́bùyóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

20. Nígbà náà ni Bálámù rí Ámálékì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:“Ámálékì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀ èdè,ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”

21. Nígbà náà ní ó rí ará Kénitì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:“Ibùgbé rẹ ní ààbò,ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;

22. ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ará Kenítì ni yóò di píparunnígbà tí Áṣúrì bá mú yín ní ìgbékùn.”

23. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:“Áì, ta ni ó lè yè nigbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?

24. Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdó kọ̀ Kítímù;wọn yóò ṣẹ́gun Áṣù àti Ébérì,ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”

25. Nígbà náà ni Bálámù dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Bálákì sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 24