Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 23:23-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù,tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì.Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì, ‘Wo ohun tí Olúwa ti ṣe!’

24. Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún;wọ́n dìde bí i kìnnìúntí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹtàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa.”

25. Nígbà náà ni Bálákì sọ fún Bálámù pé, “O ko fi wọ́n bú tàbí bùkún wọn rárá!”

26. Bálámù dáhùn pé, “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé mo gbọdọ̀ Ṣe ohun tí Olúwa bá sọ?”

27. Nígbà náà Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”

28. Bálákì gbé Bálámù wá sí orí òkè Péórì, tí ó kọjú sí ihà.

29. Bálámù sọ pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.”

30. Bálákì sì ṣe bí Bálámù ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 23