Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 23:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Bálákì ṣe bí Bálámù ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3. Nígbà náà Bálámù sọ fún Bálákì pé, “Dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn, mí màá sọ fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

4. Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Bálámù sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ.”

5. Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Bálámù ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”

6. Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Móábù.

7. Nígbà náà ni Bálámù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ jáde wí pé:“Bálákì mú mi láti Árámù wá,ọba Móábù láti òkè ìlà oòrùn wáÓ wí pé, ‘Wá fi Jákọ́bù bú fún mi;wá, kí o sì jẹ́rì i sí Ísírẹ́lì.’

8. Báwo ní èmi ó ṣe fi búàwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wíàwọn tí Olúwa kò bá wí?

9. Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè.

10. Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bùtàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì?Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́,kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”

11. Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12. Ó sì dáhùn wí pé, “Sé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 23