Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:27-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé:“Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò.

28. “Iná jáde láti Hésíbónì,ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì.Ó jó Árì àti Móábù run,àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì.

29. Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù!Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì!Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnringẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì.

30. “Ṣùgbọ́n ati bì wọ́n ṣubú;A ti pa wọ́n run títí dé Díbónì.A sì ti run wọ́n títí dé Nófà, tí ó sì fí dé Médébà.”

31. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ilẹ̀ Ámórì.

32. Lẹ́yìn ìgbà tí Mósè rán wọn lọ sí Jésírélì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gba àwọn agbégbé tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Ámórì tó wà níbẹ̀ jáde.

33. Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìn dà wọ́n sì gòkè lọ sí Básánì, Ógì ọba ti Básánì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wọ́de ogun jáde lati pàdé wọn ní ojú ogun ní Édírélì.

34. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi í lé ọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. Ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì ẹni tí ó ń jọba ní Hésíbónì.”

35. Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọn kò fi ẹnìkankan sílẹ̀. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21