Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Àmọ́ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Ánónì lọ dé Jábókù, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.

25. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ìlú Ámórì wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Hésíbónì, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.

26. Hésíbónì ni ìlú Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ó bá ọba ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Ánónì.

27. Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé:“Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò.

28. “Iná jáde láti Hésíbónì,ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì.Ó jó Árì àti Móábù run,àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì.

29. Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù!Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì!Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnringẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21