Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó pa run.”

3. Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì fi àwọn ará Kénánì lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátapáta; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Hómà.

4. Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hórì lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Édómù. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;

5. wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Olúwa àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

6. Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárin wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kú.

7. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

8. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

9. Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

10. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21