Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọba Árádì ará Kénánì, tí ń gbé ní Gúúsù gbọ́ wí pé Ísírẹ́lì ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Átarímù, ó bá Ísírẹ́lì jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn.

2. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó pa run.”

3. Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì fi àwọn ará Kénánì lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátapáta; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Hómà.

4. Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hórì lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Édómù. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;

5. wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Olúwa àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21