Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 20:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní osù kìn-ní-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Ísírẹ́lì gúnlẹ̀ sí pápá Sínì, wọ́n sì dúró ní Kádésì. Níbẹ̀ ni Míríámù kú, wọ́n sì sin ín.

2. Nísinyìí kò sì sí omi fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kóra wọn jọ lòdì sí Mósè àti Árónì,

3. Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú Olúwa!

4. Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí?

5. Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Éjíbítì wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èṣo àjàrà tàbí pamonganati. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhín-ín!”

6. Mósè àti Árónì kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.

7. Olúwa sọ fún Mósè pé,

8. “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Árónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ójú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu”

9. Báyìí ni Mósè mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ fún un.

10. Òun àti Árónì pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mósè sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yín ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

11. Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 20