Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 2:27-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì.

28. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

29. Ẹ̀yà Náfítanì ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Náfítanì ni Áhírà ọmọ Énánì.

30. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-egbéje (53,400).

31. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rún-ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.

32. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín àádọ́ta (603,550).

33. Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Léfì papọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

34. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì se gbogbo ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 2