26. A ó dárí ji gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn nítorí pé ní àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n sẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà.
27. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló sẹ̀ ní àìròtẹ́lẹ̀, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
28. Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú Olúwa fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dárí jì í.
29. Òfin kan náà ló wà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, yálà ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò tí ń gbé láàrin yín.
30. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀
31. Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’ ”
32. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísirẹ́lì wà nínú ihà, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi ní ọjọ́ Ísínmì.
33. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣa igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Árónì àti ṣíwájú gbogbo ìjọ ènìyàn;
34. Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.
35. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Kíkú ni ọkùnrín náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sọ ọ́ lókúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”