Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 13:4-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí:láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì Ṣámuá ọmọ Ṣákúrì;

5. láti inú ẹ̀yà Símónì, Ṣáfátì ọmọ Hórì;

6. láti inú ẹ̀yà Júdà, Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè;

7. Láti inú ẹ̀yà Ísíkárì, Ígálì ọmọ Jósẹ́fù;

8. Láti inú ẹ̀yà Éfúráímù, Ósíà ọmọ Núnì;

9. Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọ Raù;

10. Láti inú ẹ̀yà Ṣébúlónì, Gádíélì ọmọ Ṣódì;

11. Láti inú ẹ̀yà Mánásè, (ẹ̀yà Jósẹ́fù), Gádì ọmọ Ṣúsì;

12. Láti inú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọ Gémálì;

13. Láti inú ẹ̀yá Áṣérì, Ṣétúrì ọmọ Míkáẹ́lì.

14. Láti inú ẹ̀yà Náfítanì, Nábì ọmọ Fófósì;

15. Láti inú ẹ̀yà Gádì, Géúlì ọmọ Mákì.

16. Wọ̀nyí ni orukọ àwọn ènìyàn tí Mósè rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Ósísà ọmọ Núnì ni Mósè sọ ní Jóṣúà.)

17. Nígbà tí Mósè rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà Gúúsù lọ títi dé àwọn ìlú olókè

18. Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.

19. Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?

20. Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èṣo àjàrà gíréépù.)

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 13