Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 13:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kénánì wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

3. Mósè sì rán wọn jáde láti Aginjù Páránì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

4. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí:láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì Ṣámuá ọmọ Ṣákúrì;

5. láti inú ẹ̀yà Símónì, Ṣáfátì ọmọ Hórì;

6. láti inú ẹ̀yà Júdà, Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè;

7. Láti inú ẹ̀yà Ísíkárì, Ígálì ọmọ Jósẹ́fù;

8. Láti inú ẹ̀yà Éfúráímù, Ósíà ọmọ Núnì;

9. Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọ Raù;

10. Láti inú ẹ̀yà Ṣébúlónì, Gádíélì ọmọ Ṣódì;

11. Láti inú ẹ̀yà Mánásè, (ẹ̀yà Jósẹ́fù), Gádì ọmọ Ṣúsì;

12. Láti inú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọ Gémálì;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 13