Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 12:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.

10. Nígbà tí ìkúùkù kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Míríámù di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Árónì sì padà wo Míríámù ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,

11. Ó sì sọ fún Mósè pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn.

12. Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”

13. Torí èyí Mósè sì kígbe sí Olúwa, “Olúwa, dákun mú un lára dá!”

14. Olúwa sì dá Mósè lóhùn, “Bí bàbá rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 12