Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 12:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrin yínÈmi Olúwa a máa fara à mi hàn án ní ojúran,Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.

7. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi:ó jẹ́ olótítọ́ nínú gbogbo ilé mi.

8. Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,ó rí àwòrán OlúwaKí ló wá dé tí ẹ̀yin kò se bẹ̀rùláti sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”

9. Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 12