Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 10:28-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29. Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”

30. Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

31. Mósè sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú ihà, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa.

32. Bí o bá báwa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

33. Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí Ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.

34. Ìkúùkù Olúwa wà lórí wọn lọ́sán nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

35. Nígbàkigbà tí àpótí Ẹ̀rí bá gbéra Mósè yóò sì wí pé;“Dìdé, Olúwa!Kí a tú àwọn ọ̀ta rẹ ká,kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

36. Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé;“Padà, Olúwa,Sọ́dọ̀ àwọn àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 10