Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 10:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kóhátì tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabánákù dúró kí wọn tó dé.

22. Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Éfúráímù ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisámà ọmọ Ámíhúdì ni ọ̀gágun wọn.

23. Gàmálíélì ọmọ Pédásúrì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Mánásè.

24. Ábídánì ọmọ Gídíónì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

25. Lákòótan, àwọn ọmọ ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dánì lábẹ́ ọ̀págun wọn. Áhíésérì ọmọ Ámíṣádárì ni ọ̀gágun wọn.

26. Págíélì ọmọ Ókíránì ni ìpín ti ẹ̀yà Ásérì,

27. Áhírà ọmọ Énánì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Náfítanì;

28. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29. Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”

30. Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 10