Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 10:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùukù kúrò lórí tabánákù Ẹ̀rí.

12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbéra kúrò ní ihà Sínáì wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùukù fi dúró sí ihà Páránì.

13. Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.

14. Àwọn ìpín ti ibùdó Júdà ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Náṣónì ọmọ Ámínádábù ni ọ̀gágun wọn.

15. Nẹ̀taníẹ́lì ọmọ Ṣúárì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Ísákárì;

16. Élíábù ọmọ Hélónì ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì.

17. Nígbà náà ni wọ́n sọ tabánákù kalẹ̀ àwọn ọmọ Gáṣónì àti Mérárì tó gbé àgọ́ sì gbéra.

18. Àwọn ìpín ti ibùdó ti Rúbẹ́nì ló gbéra tẹ̀le wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Élísúrì ọmọ Sédúrì ni ọ̀gágun wọn.

19. Ṣélúmíélì ọmọ Surisádáì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Símónì.

20. Élíásáfì ọmọ Déúélì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gáádì.

21. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kóhátì tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabánákù dúró kí wọn tó dé.

22. Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Éfúráímù ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisámà ọmọ Ámíhúdì ni ọ̀gágun wọn.

23. Gàmálíélì ọmọ Pédásúrì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Mánásè.

24. Ábídánì ọmọ Gídíónì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

25. Lákòótan, àwọn ọmọ ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dánì lábẹ́ ọ̀págun wọn. Áhíésérì ọmọ Ámíṣádárì ni ọ̀gágun wọn.

26. Págíélì ọmọ Ókíránì ni ìpín ti ẹ̀yà Ásérì,

27. Áhírà ọmọ Énánì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Náfítanì;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 10