Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 10:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé:

2. Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o má a lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.

3. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé ṣíwájú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

4. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náa ni àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò péjọ ṣíwájú rẹ.

5. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà oòrùn ni yóò gbéra.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 10