Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 10:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé:

2. Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o má a lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.

3. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé ṣíwájú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

4. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náa ni àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò péjọ ṣíwájú rẹ.

5. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà oòrùn ni yóò gbéra.

6. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra.

7. Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má se fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀.

8. “Àwọn Ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀.

9. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀ta tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì ránti yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta yín.

10. Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

11. Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùukù kúrò lórí tabánákù Ẹ̀rí.

12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbéra kúrò ní ihà Sínáì wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùukù fi dúró sí ihà Páránì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 10