Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 8:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípaṣẹ̀ Mósè, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje

15. àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn-án kálẹ̀ ní gbogbo ìlúu wọn àti ní Jérúsálẹ́mù: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olífì àti ẹ̀ka igi olífì ìgbẹ́, àti láti inú máítílì, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

16. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Éúfúrémù.

17. Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú un wọn. Láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọ Núnì títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.

18. Ẹ́sírà kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn. Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpèjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

Ka pipe ipin Nehemáyà 8