gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè-Omi. Wọ́n sọ fún Ẹ́sírà akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mósè jáde, èyí tí Olúwa ti pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.