Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 11:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà. Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run.

23. Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ọ wọn.

24. Petaiayọ̀ ọmọ Meṣeṣabélì, ọ̀kan nínú àwọn Ṣérà ọmọ Júdà ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

25. Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Júdà tí ń gbé Kíríátí-Ábà, àti àwọn ìletò agbégbé e rẹ̀, ní Díbónì àti ìletò rẹ̀, ní Jékábíṣéélì.

26. Ní Jéṣúà, ní Móládà, ní Bétípélétì

27. Ní Háṣárì Ṣúálì, ní Bíáṣébà àti àwọn agbégbé rẹ̀.

28. Ní Ṣíkílágì, ní Mékónà àti àwọn ìletò rẹ̀,

29. ní Ẹni-rímónì, ní ṣórà, ní Járímútì,

30. Ṣánóà, Ádúlámù àti àwọn ìletò o wọn, ní Lákísì àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Ásékà àti awọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Bíáṣébà títí dé àfonífojì Hínómì.

31. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Gébì ń gbé ní Míkímásì, Áíjà, Bétélì àti àwọn ìletò rẹ̀.

32. Ní Ánátótì, Nóbù àti Ánáníyà,

33. Ní Háṣórì Rámà àti Gítaímù,

34. Ní Hádídì, Ṣébóimù àti Nébálátì,

35. Ní Lódì àti Ónò, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.

36. Nínú ìpín àwọn ọmọ Léfì ni Júdà tẹ̀dó sí Bẹ́ńjámínì.

Ka pipe ipin Nehemáyà 11