Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 1:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì pada sí agbégbé ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jérúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná ṣun ẹnu ibodè rẹ̀.”

4. Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì ṣunkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run.

5. Nígbà náà ni mo wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́.

6. Jẹ́ kí etíì rẹ kí ó ṣi sílẹ̀, kí ojúù rẹ kí ó sì sí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Ísírẹ́lì àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.

7. Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ mọ́.

Ka pipe ipin Nehemáyà 1