Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 3:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní otitọ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Olúwa wò ni a dá sí.’ ”

16. Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, ti wọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.

17. “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò ń sìn ín sí.

18. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrin olódodo àti ẹni búburú, láàrin ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.

Ka pipe ipin Málákì 3