Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ Olúwa sí Ísírẹ́lì láti ẹnu Málákì.

2. “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni Olúwa wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’“Ísọ̀ kì í ha ṣe arákùnrin Jákọ́bù bí?” ni Olúwa wí. “Ṣíbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jákọ́bù,

3. ṣùgbọ́n Ísọ̀ ni èmi kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè-ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akáta ihà.”

4. Édómù lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.”Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé: “Àwọ́n lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní Ilẹ̀ Búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú Olúwa.

5. Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni Olúwa, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Ísírẹ́lì.’

6. “Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ-ọ̀dọ̀ a sì máa bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Bí èmí bá jẹ́ baba ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí mi dà? Bí èmi bá sì jẹ́ ọ̀gá ọlá, tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ ọ̀ mi.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ ọ̀ rẹ?’

7. “Ẹ̀yín gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ ẹ̀ mi.“Ẹ̀yín sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’“Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn.

Ka pipe ipin Málákì 1