Léfítíkù 8:35-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
35. Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún mi ni èyí.”
36. Báyìí ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pa láṣẹ láti ẹnu Mósè.