Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 7:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún rírú ẹbọ ẹ̀bi, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ:

2. Níbi tí wọn ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí ẹ ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí ẹ sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

3. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ ni kí ẹ sun, ọ̀rá ìrù rẹ̀ àti ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀.

4. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti ọ̀rá to bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín.

5. Àlùfáà yóò sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀bi ni.

Ka pipe ipin Léfítíkù 7