Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 3:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ọrẹ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.

15. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

16. Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa.

17. “ ‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé: Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Léfítíkù 3