Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 26:39-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò sòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀ta yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn babańlá yín.

40. “ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti babańlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.

41. Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀ta wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

42. Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jákọ́bù àti pẹ̀lú Ísáákì àti pẹ̀lú Ábúráhámù: Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.

43. Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófò láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórira àwọn àṣẹ mi.

44. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀ta wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kóríra wọn pátapáta: èyi tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Ọlọ́run wọn

45. Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú babańlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì lójú gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

46. Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mósè ní orí òkè Sínáì láàrin òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Léfítíkù 26