Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 25:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè ní orí òkè Sínáì pé,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín: ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún Olúwa.

3. Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi gbin èso ọgbà yín, kí ẹ sì kórè èso wọn.

4. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún Olúwa. Ẹ má ṣe gbin èso ọgbà yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ rò wọ́n.

Ka pipe ipin Léfítíkù 25